Proverbs 24

1Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú
má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;
2Nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú,
ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.

3Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́
nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀;
4Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún
pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.

5Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀,
ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i
6Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà:
nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.

7Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè
àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.

8Ẹni tí ń pète ibi
ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.
9Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.

10Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú
báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!
11Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là;
fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.
12Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,”
ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n?
Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?

13Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,
oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
14Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ
bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ
ìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo.

15Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburú
láti gba ibùjókòó olódodo,
má ṣe fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ;
16nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà
méje, yóò tún padà dìde sá á ni,
ṣùgbọ́n ìdààmú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.

17Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú;
nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀.
18Àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínú
yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

19Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi
tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,
20nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú
a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.

21Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi,
má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun.
22Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn,
ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?

Àwọn ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n mìíràn

23Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n:

láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá:
24Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre”
àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
25Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,
ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.

26Ìdáhùn òtítọ́
dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu.

27Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ
sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára;
lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

28Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí,
tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
29Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;
Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”

30Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,
mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn;
31ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,
koríko ti gba gbogbo oko náà
32Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsi
mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;
33oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi
34Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè
àti àìní bí olè.
Copyright information for YorBMYO